Description
EMI MIMO
ÌFIHÀN
Awon omoléyin Krisiti ayé òde òní kò télé ìlànà Emí Mímó bí ó ti tó. Awon omo ijó kúná láti lo Emí Olorun tí ó jé Emi Mímó. Eyi ni Emí Olorun so nígbà tí mo n ro ȧkòrí tó dale ‘’Emi Mimó’’.
Emi mimo jé okan lára Métalokan; Ó ti wà kí işèdá ayé tó bèrè. Nínú ìwé Génésísi 1:1-3, Bibéli wipe:
“Ni àtètèkose, Olorun dá orun àti ayé. Ayé si wà ní júujùu, ó sì sófo, okunkun si wà lójú ibú: Emi Olorun si nrababa loju omi. Olorun si wipé, kí ìmolè̟ kí ó wà: ìmolè sì wà.”
Emi Mimó tí ó jé Emi Olorun bèrè işé láti ipinlèsę ayé nígbà tí ayé kò ní òdiwon ti okunkun si gba gbogbo ayé. Ewè, Emí Mimó nipase imólè mú kí ayé wà ní òdiwon. Ní òtító, ti kò bá Emi Mimó, ayé kò lè wà lónii, Sugbon ògo Olorun mú kí ohun gbogbo lo déedé, Emí Olorun rá bábà lójú omi, imolè sì wonú ayé wa.
Emi Mimó yii kan náà, nígbà tí Jésù Kristi fi ògo Rè sile ni orun tí Ógbé àwò iránsé wò wá sínú ayé, èyí ló fún-Un ni agbára lati kú fún omo eniyan, lójúná láti kó èsè ayé lo.
“Eni tí ó tilè jé àwòrán Olorun, Ti kò kȧá sí ìwòra láti bá Olórun dogba: Şùgbón Ó bó ògo Rè sílè, ó sì mú àwò iránṣé, A sì sé E ní àwò ènìyàn. Nígbà tí a si ti ri I ní ìrí ènìyàn, Ó rę ara Rè sílè, ó sì teriba títí di ojú ikú, Àní ikú ori igi àgbélébùú” – Filipi 2:6-8.
Ní Máttéù 1:18-22, Bíbéli so wípé, Olùgbàlà wá sínú ayé nipasé wúndíá ní ilè Israeli, eni tí ó rí ojú rere, Emí Mímó siji bò, eni tí ó bí Jésù Kristi, Olùgbàlà aráyé.
“Bí ìbí Kristi ti ri nìyí: Ní àkókò tí a fé Maríà iyá Rè fún Jóséfù, A rí i, ó lóyún láti owo Emi Mimó wá. Jóséfù ọkọ rè tí í şe olódodo ènìyàn kò si fé dójú tì í ní gbangba, O fè kòó sílè ní ìkòkò. Şùgbón nígbà tí ó n ro nnkan wònyí, Wò ó, angeli Oluwa yo sí i ní ojú álá Ó sì wipé, Jósefù, ìwo̟ o̟mo̟ Dáfidi, Má fòyà láti mú Máríà aya re sí òdò: Nítorí èyí tí ó yún nínú rè, láti owo Èmí Mímó ni. Yóò si bí ọmọkùnrin kan, Jésù ni ìwo ó pe Orúkọ rè: Nítorí Oun ni yóò gba àwọn ènìyàn rèlà kúrò nínú èsè won. Gbogbo èyí sì şe, kí èyí tí a sọ láti ò̟dò̟ Oluwa wa ni enu wòlíì kí ó lè se pé,” — Matteu 1:18-22.
Olùfé òwón, láisí Emí Mímó, òfo ni ènìyàn. Nígbà tí Jòhánù Onitèbomi wá sí ayé, Olórun rán-an sáájú Olùgbàla, sùgbón ó so nnkan tí ó sòro láti gbàgbó gégé bí Matteu 3:11 se wí:
“Lótito ni èmí n fi omi baptisi yin fún irònúpiwàdà, sùgbón enìkan tí ó pò jù mí ló n bò léyìn mi, bàtà eni ti èmi kò tóo gbé, òun ni yóò fi Emí Mímó àti iná baptisi yin.”
Nítorí èyí, nípa oore-òfé Olórun, a ó se àtúpalè iwé yìí nípasè àkòrí wònyí: Isé Emí Mímó, Agbára Emí Mímó, Ebùn Emí Mímó àti Eso Emí Mímó.
Kí Oluwa bùkún yín lórúkọ Jésù (Àmín).
Reviews
There are no reviews yet.