IWE IYE

IWE IYE

3,000.00

Àwọn kókó miíràn wà tí a ó tún jíròrò lé nínú ìwé yìí. Kí gbogbo wa di eni ìbùkún bí a ti n jiròrò ìwé tó lágbára yìí lóruko Jésù (Àmín).

Category:

Description

IWE IYE

ÌFIHÀN

Òrò Olorun so pé: “Enikéni tí orúkọ rè kò bá sí nínú ìwé iyè, a ó so ó sínú adágún iná”                  Ìfihan 20:15.

Iwé wo ni ìwé iyè? Iwé iyè ni ìwé tí orúkọ àwọn eni mímó̟ wà. Ìwé yii kò sí ní ayé. Ìkáwo Olorun ló wà. Inú ìwé yii ni won yóò ti se iìdájó gbogbo èdá. Bíbéli so pé:

 

“Mo sì rí àwọn òkú àti èwę àti àgbà, Wón dúró níwájú ìté, A sì sí àwọn ìwé sílè. A sì si àwọn ìwé mìíràn kan sílè Tíí se ìwé ìyè: A sì se ìdájó fún àwọn òkú láti inú ohun ti a ti ko sí àwọn ìwé náà gégé bì isé o̟wó̟ wọn.” — Ìfihàn 20:12.

 

Òkun yóò jò̟wó̟ àwọn tó kú sínú rè. Won yóò jò̟wó̟ àwọn tó rì nínú oko ojú omi, oko òfúrufú Malaysia tó jábó sínú okun àti ogòòrò àwọn tó kú ni won yóò jowo wọn lójó idájó. Elégbéjegbé àwọn tó kú nínú ijàmbá oko ojú omi tó ri ní Libya, àwọn tó kú nínú isèlè ikún omi ní Phillipine àti

gbogbo àwọn ti ikún omi gbé lọ ni won yóò kojú idájó lójó náà.

 

Lójó tí a wí yii, omi yóò gbó òrò Olórun, yóò si tú àwon tó wà nínú ìgbèkun silè. Nínú Iwé yìí lá ó ti se idájó gbogbo ènìyàn. Gbogbo okán tó se tán láti lo orun rere ni orúkọ won gbo̟dò̟ wà nínu iwé yií. Nítorí náà, mo fé kí ę gbà pèlú mi pé gbogbo àsotélé tó wà nínú Bíbéli Mímó ló ti wá sí imúse, sùgbón ohun kan tí kò tii wá sí ìmuse ni igbàsókè àwọn àyànfé èyí tó wà ní ìkáwó Jésù Krísti Olúwa wa. Awọn ènìyàn tí orúkọ won máa wà nínú ìwé iyè ni àwọn eni iràpadà, àwọn tó ní èso èmí mésàn-án, àwọn tó sá fún Èṣù àti omo ogun rè.

 

Àwọn kókó miíràn wà tí a ó tún jíròrò lé nínú ìwé yìí. Kí gbogbo wa di eni ìbùkún bí a ti n jiròrò ìwé tó lágbára yìí lóruko Jésù (Àmín).

 

Wòlíi Samson Olúwamódedé

Reviews

There are no reviews yet.

Be the first to review “IWE IYE”

Your email address will not be published. Required fields are marked *